Gospel Music Nigerian Gospel Songs Ebenezer Obey – The Horse, The Man & The Son

Ebenezer Obey – The Horse, The Man & The Son

Download The Horse, The Man & The Son Mp3 by

Here's a song by a Nigerian gospel and juju musician, popularly known as Chief Commander whose song has been a blessing to lives. The song is titled “The Horse, The Man & The Son“. He formed the juju band, the International Brothers, in 1964 and since then use his miliki style of music to bless lives and pass great information always.

Get Audio Mp3, Share, Stream, and be blessed.

DOWNLOAD HERE

Lyrics: The Horse, The Man & The Son by

Ko s'ogbon to le da ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o

Ko s'ogbon to le da ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o

L'ojo t'aba bi ‘mo tuntun si ile aye
T'onille t' alejo lo ma ki ni kuu ewu
L'ojo t'aba bi ‘mo tuntun si ile aye
T'onille t' alejo lo ma ki ni kuu ewu Ota omode bere lati ni bi irakoro
Ka da ni l'ojeun nu oti bere ota nini
Ka da ni l'omi nu oti bere ota nini
O ti bo so owo aye

T'omo naa ba ti bere si ni rin
To ba l'egbe to n jo sere l'aarin adugbo
Ti obi re ba le ra keke fun
O ti bo so owo aye
To ba ni ko gbe wa ko jo fi sere
To ba ni rara oti d'ota won
O ti bo so owo aye
Won ani ma gbe keke e lo
A'o ba e sere mo

Ti ojo ba g'ori ojo ti omo naa ba d'agba
To bere si ni re ile iwe to f'oju si eko rẹ to n se dede
Ti wo n ba se idanwo to ba se ipo kinii
O ti di ota on'ipo k'efa won fun l'oruko
Won ni omo teacher ni

A s'eyin wa a s'eyin bo omo ‘jo si bere ise
Oga ile ise ni ko ma de b'ise ni agogo mejo
O n se dede o de b'ise ni akoko kii pa t' ise je
Awon ole afajo won fun loruko
Won ni omo manager ni
O ti bo s'owo aye

Omo to n sise dede o ye ko ni asiko igbadun
Igba ti o fi j'aye

To ba lo si party nibi ti won je igbadun
To ba ni ki loo mu lo ba ni Coca-Cola won ni ko maye je jedi-jedi lo ma pa
To ba lo si party nibi ti won je igbadun
To ba ni ki loo mu lo ba ni Coca-Cola won ni ko maye je jedi-jedi lo ma pa

To ba tun je oga oni faaji to n j'aye dede
Champagne pelu Schnapps ti o fi n yonu
Heineken beer Star lager Top beer
Becks beer pelu Guinness gbogbo re l'oba l'ara mu
Awon eda Adamo won fun l'oruko
Oti l'alakori f'owo re mu

To ba tun wa lo je agba man to lo aso asiko
To tu l'ori obinrin won fun l'oruko
Igberaga ti p'oju ko mo ju obinrin lo sina l'arakori f'owo e se

To ba tun je oni suru to ka iwe to gb'oye repete
To n d'ogbon jaye ti ki s'aapon ti ko feran obirin
Awon eda Adamo won fun l'oruko
Alakori akada ni se lo n roju koikoi

Omu mi ranti itan baba kan pelu omo re ti won sin ketekete
Omu mi ranti itan baba kan pelu omo re ti won sin ketekete
Eshin pelu ketekete o da bi motor to won gun lo s'ode
Eshin pelu ketekete l'aye ojo yen o da bi motor ti won gun lo s'ode

Ketekete ti d'agba baba pelu omo e ba mura ode won fe r'irin ajo kan
Gege bi agbalagba baba gun ketekete omo re rin tele lo
Bi won se rin s'iwaju die won pade Adamo eda omo araye
Omo araye ni Ow Baba agbalagba omo re n'ile iwo n gun ketekete

Baba ba bo s'ile lori ketekete l'oba gbé omo re s'ori ketekete
Won ba mu irin ajo won pon
Won lo won lo
Bi won se rin s'iwaju die won tun pade Adamo eda omo araye
Omo araye tu ni Ow
Baba omugo o rin n'ile omo gun ketekete

Baba ba tun sure o gb'omo s'ile
O sare gun ketekete o tun gb'omo s ori ketekete
Eni meji-reji lori ketekete
Won mu irin ajo wo pon
Won lo won lo
Bi won se tu rin s'iwaju die won pade Adamo eda omo araye
Omo araye tu ni Ow
Omo ati baba alaini anu ni yin
Eyin mejeji lori ketekete e fe pa ketekete ni

Baba ba w'oke titi
Oni ma te yin l'orun eyin eda omo araye
Baba ba gb'omo s'ile lori ketekete
Ohun naa bo s'ile lori ketekete
Ketekete n lo l'ofo baba pelu omo re won fi ese rin tele

Bi won se tu rin s'iwaju die won pade Adamo eda omo araye
Omo araye tu ni Ow
Eyin mejeji eru aye ni yin
E rin n'ile ketekete n lo l'ofo

Baba pelu omo ie gege bi mo ti wi won bo s'ile
Ketekete n lo niwaju won fi ese rin tele
Won tun rin s'iwaju die won pade Adamo eda omo araye
Omo araye ni Ow
Eyin mejeji eru aye ni yin
E rin n'ile ketekete n lo l'ofo

Baba ba b'oju woke o fe ranti orin Chief Commander
Oni edakun e fe yi k'ogbon

Ko s'ogbon to le da ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o
Ko s'ogbon to le da ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o

Ko s'ogbon to le da ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o
Ko s'ogbon to le da ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o

Ile aye fun igba die ni o omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o omo araye e se re o
A fi ka w'uwa rere rere lo pe omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o omo araye e se re o

Commander Ebenezer do your best and leave the rest
Commander Ebenezer do your best and leave the rest

Ile aye fun igba die ni o omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o omo araye e se re o
Rere lo pe a fi ka ma w'uwa rere omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o omo araye e se re o

Comment below with your feedback and thoughts on this post.